2 Kronika 33:9
2 Chronicles 33:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
2 Chronicles 33:9 in English
2 Chronicles 33:9 · Berean Standard Bible
So Manasseh led the people of Judah and Jerusalem astray, so that they did greater evil than the nations that the LORD had destroyed before the Israelites.
Context
7Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. 8Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.” 9Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 10Olúwa bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i. 11Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.