2 Kronika 33:13
2 Chronicles 33:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.
2 Chronicles 33:13 in English
2 Chronicles 33:13 · Berean Standard Bible
And when he prayed to Him, the LORD received his plea and heard his petition; so He brought him back to Jerusalem and to his kingdom. Then Manasseh knew that the LORD is God.
Context
11Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli. 12Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀. 13Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run. 14Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí, ó mọ odi kan lẹ́yìn ìlú Dafidi, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, àní ní àtiwọ ẹnu ibodè ẹja, ó sì yí orí òkè Ofeli ká; ó sì mọ ọ́n ga sókè gidigidi, ó sì fi balógun sínú gbogbo ìlú olódi Juda wọ̀n-ọn-nì. 15Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjèjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jerusalẹmu; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.