Native Bible

2 Chronicles 32:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀:

2 Chronicles 32:9 in English

2 Chronicles 32:9 · Berean Standard Bible

Later, as Sennacherib king of Assyria and all his forces besieged Lachish, he sent his servants to Jerusalem with a message for King Hezekiah of Judah and all the people of Judah who were in Jerusalem:

Context

7“Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Asiria àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ. 8Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Olúwa Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí. 9Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀: 10“Èyí ni ohun tí Sennakeribu ọba Asiria wí, ‘Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbógun sí?’ 11Nígbà tí Hesekiah wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria,’ ó ń ṣì yín tọ́ ṣọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.