2 Kronika 32:4
2 Chronicles 32:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ náà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí.
2 Chronicles 32:4 in English
2 Chronicles 32:4 · Berean Standard Bible
Many people assembled and stopped up all the springs and the stream that flowed through the land. “Why should the kings * of Assyria come and find plenty of water?” they said.
Context
2Nígbà tí Hesekiah rí i pé Sennakeribu ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lórí Jerusalẹmu, 3Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. 4Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ náà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí. 5Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta. 6Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pè wọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dafidi. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.