Native Bible

2 Chronicles 32:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2 Chronicles 32:33 in English

2 Chronicles 32:33 · Berean Standard Bible

And Hezekiah rested with his fathers and was buried in the upper tombs of David’s descendants. All Judah and the people of Jerusalem paid him honor at his death. And his son Manasseh reigned in his place.

Context

31Ṣùgbọ́n nígbà tí a rán àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Babeli láti bi í lérè nípa àmì ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀. 32Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Hesekiah àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Isaiah ọmọ Amosi nínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli 33Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.