Native Bible

2 Chronicles 32:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran.

2 Chronicles 32:28 in English

2 Chronicles 32:28 · Berean Standard Bible

He also made storehouses for the harvest of grain and new wine and oil, stalls for all kinds of livestock, and pens for the flocks.

Context

26Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah. 27Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye. 28Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran. 29Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Ọlọ́run ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá. 30Hesekiah ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gihoni. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dafidi. Ó ṣe àṣeyọrí rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.