2 Kronika 32:12
2 Chronicles 32:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé Hesekiah fúnra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lórí rẹ̀’?
2 Chronicles 32:12 in English
2 Chronicles 32:12 · Berean Standard Bible
Did not Hezekiah himself remove His high places and His altars and say to Judah and Jerusalem, ‘You must worship before one altar, and on it you shall burn sacrifices’?
Context
10“Èyí ni ohun tí Sennakeribu ọba Asiria wí, ‘Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbógun sí?’ 11Nígbà tí Hesekiah wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria,’ ó ń ṣì yín tọ́ ṣọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ. 12Ṣé Hesekiah fúnra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lórí rẹ̀’? 13“Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn baba mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi? 14Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.