Native Bible

2 Chronicles 32:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Hesekiah ti fi òtítọ́ ṣe, Sennakeribu ọba Asiria wá ó sì gbógun ti Juda. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ara rẹ̀.

2 Chronicles 32:1 in English

2 Chronicles 32:1 · Berean Standard Bible

After all these acts of faithfulness, Sennacherib king of Assyria came and invaded Judah. He laid siege to the fortified cities, intending to conquer them for himself.

Context

1Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Hesekiah ti fi òtítọ́ ṣe, Sennakeribu ọba Asiria wá ó sì gbógun ti Juda. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ara rẹ̀. 2Nígbà tí Hesekiah rí i pé Sennakeribu ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lórí Jerusalẹmu, 3Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.