Native Bible

2 Chronicles 30:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria.

2 Chronicles 30:6 in English

2 Chronicles 30:6 · Berean Standard Bible

So the couriers went throughout Israel and Judah with letters from the king and his officials, which read: “Children of Israel, return to the LORD, the God of Abraham, Isaac, and Israel, so that He may return to those of you who remain, who have escaped the grasp of the kings of Assyria.

Context

4Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn. 5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. 6Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria. 7Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí. 8Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé. Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.