2 Kronika 30:22
2 Chronicles 30:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.
2 Chronicles 30:22 in English
2 Chronicles 30:22 · Berean Standard Bible
And Hezekiah encouraged all the Levites who performed skillfully before the LORD. For seven days they ate their assigned portion, sacrificing fellowship offerings and giving thanks to the LORD, the God of their fathers.
Context
20Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá. 21Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa. 22Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn. 23Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́. 24Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.