Native Bible

2 Chronicles 30:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli.

2 Chronicles 30:1 in English

2 Chronicles 30:1 · Berean Standard Bible

Then Hezekiah sent word throughout all Israel and Judah, and he also wrote letters to Ephraim and Manasseh inviting them to come to the house of the LORD in Jerusalem to keep the Passover of the LORD, the God of Israel.

Context

1Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 2Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì. 3Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.