2 Kronika 29:6
2 Chronicles 29:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.
2 Chronicles 29:6 in English
2 Chronicles 29:6 · Berean Standard Bible
For our fathers were unfaithful and did evil in the sight of the LORD our God. They abandoned Him, turned their faces away from the dwelling place of the LORD, and turned their backs on Him.
Context
4Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Lefi, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà-oòrùn. 5Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ilé Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ baba mi jáde kúrò ní ibi mímọ́. 6Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i. 7Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Israẹli. 8Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.