Native Bible

2 Chronicles 28:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria.

2 Chronicles 28:8 in English

2 Chronicles 28:8 · Berean Standard Bible

Then the Israelites took 200,000 captives from their kinsmen—women, sons, and daughters. They also carried off a great deal of plunder and brought it to Samaria.

Context

6Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀. 7Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba. 8Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria. 9Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odedi wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Samaria. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run baba yín bínú sí Juda ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run. 10Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.