2 Kronika 28:5
2 Chronicles 28:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku. Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.
2 Chronicles 28:5 in English
2 Chronicles 28:5 · Berean Standard Bible
So the LORD his God delivered Ahaz into the hand of the king of Aram, who attacked him and took many captives to Damascus. Ahaz was also delivered into the hand of the king of Israel, who struck him with great force.
Context
3Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hinnomu, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli 4Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ́n nì lórí òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 5Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku.
Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. 6Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀. 7Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.