Native Bible

2 Chronicles 28:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn.

2 Chronicles 28:18 in English

2 Chronicles 28:18 · Berean Standard Bible

The Philistines had also raided the cities of the foothills * and the Negev of Judah, capturing and occupying Beth-shemesh, Aijalon, and Gederoth, as well as Soco, Timnah, and Gimzo with their villages.

Context

16Ní àkókò ìgbà náà, ọba Ahasi ránṣẹ́ sí ọba Asiria fún ìrànlọ́wọ́. 17Àwọn ará Edomu sì tún padà wá láti kọlu Juda kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ. 18Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn. 19Olúwa sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí Olúwa. 20Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.