2 Kronika 28:12
2 Chronicles 28:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Efraimu, Asariah ọmọ Jehohanani, Berekiah ọmọ Meṣilemoti, Jehiskiah ọmọ Ṣallumu, àti Amasa ọmọ Hadlai, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀.
2 Chronicles 28:12 in English
2 Chronicles 28:12 · Berean Standard Bible
Then some of the leaders of the Ephraimites *—Azariah son of Jehohanan, Berechiah son of Meshillemoth,* Jehizkiah son of Shallum, and Amasa son of Hadlai—stood in opposition to those arriving from the war.
Context
10Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin? 11Nísinsin yìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbèkùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ń bẹ lórí yín.” 12Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Efraimu, Asariah ọmọ Jehohanani, Berekiah ọmọ Meṣilemoti, Jehiskiah ọmọ Ṣallumu, àti Amasa ọmọ Hadlai, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀. 13Wọn si wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi púpọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Israẹli.” 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógun sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.