Native Bible

2 Chronicles 27:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli.

2 Chronicles 27:3 in English

2 Chronicles 27:3 · Berean Standard Bible

Jotham rebuilt the Upper Gate of the house of the LORD, and he worked extensively on the wall at the hill of Ophel.

Context

1Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 2Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn. 3Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli. 4Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi. 5Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òsùwọ̀n alikama àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.