2 Kronika 26:7
2 Chronicles 26:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni.
2 Chronicles 26:7 in English
2 Chronicles 26:7 · Berean Standard Bible
God helped him against the Philistines, against the Arabs living in Gur-baal, and against the Meunites.
Context
5Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere. 6Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. 7Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. 8Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá. 9Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.