2 Kronika 26:17
2 Chronicles 26:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e.
2 Chronicles 26:17 in English
2 Chronicles 26:17 · Berean Standard Bible
Then Azariah the priest, along with eighty brave priests of the LORD, went in after him.
Context
15Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára. 16Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.” 19Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.