2 Kronika 26:10
2 Chronicles 26:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
2 Chronicles 26:10 in English
2 Chronicles 26:10 · Berean Standard Bible
Since he had much livestock in the foothills * and in the plain, he built towers in the desert and dug many cisterns. And since he was a lover of the soil, he had farmers and vinedressers in the hill country and in the fertile fields.
Context
8Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá. 9Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe. 11Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.