Native Bible

2 Chronicles 25:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgba ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.”

2 Chronicles 25:16 in English

2 Chronicles 25:16 · Berean Standard Bible

While he was still speaking, the king asked, “Have we made you the counselor to the king? Stop! Why be struck down?” So the prophet stopped, but he said, “I know that God has determined to destroy you, because you have done this and have not heeded my advice.”

Context

14Nígbà tí Amasiah padà láti ibi pípa àwọn ará Edomu, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn Seiri padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rú ẹbọ fún wọn. 15Ìbínú Olúwa ru sí Amasiah, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn tiwọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?” 16Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgba ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.” 17Lẹ́yìn tí Amasiah ọba Juda ti béèrè lọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá bá mi lójúkojú.” 18Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “Koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.