2 Kronika 25:11
2 Chronicles 25:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, Amasiah ko ogun rẹ jọ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lọ sí àfonífojì iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Seiri.
2 Chronicles 25:11 in English
2 Chronicles 25:11 · Berean Standard Bible
Amaziah, however, summoned his strength and led his troops to the Valley of Salt, where he struck down 10,000 men of Seir,
Context
9Amasiah sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́ ogun àwọn ọmọ Israẹli ń kọ́?”
Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.” 10Bẹ́ẹ̀ ni Amasiah, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Efraimu ká. Ó sì rán wọn lọ ilé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Juda, wọ́n sì padà lọ ilé pẹ̀lú ìbínú ńlá. 11Nígbà náà, Amasiah ko ogun rẹ jọ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lọ sí àfonífojì iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Seiri. 12Àwọn ọkùnrin Juda pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láààyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́. 13Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Amasiah ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Juda láti Samaria sí Beti-Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.