2 Kronika 24:22
2 Chronicles 24:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Sakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.”
2 Chronicles 24:22 in English
2 Chronicles 24:22 · Berean Standard Bible
Thus King Joash failed to remember the kindness that Zechariah’s father Jehoiada had extended to him. Instead, Joash killed Jehoiada’s son. As he lay dying, Zechariah said, “May the LORD see this and call you to account.”
Context
20Nígbà náà, Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Sekariah ọmọ Jehoiada wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ” 21Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa. 22Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Sakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.” 23Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun Aramu yàn láti dojúkọ Joaṣi; wọ́n gbógun ti Juda àti Jerusalẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Damasku. 24Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun Aramu ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Joaṣi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.