Native Bible

2 Chronicles 22:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n.

2 Chronicles 22:8 in English

2 Chronicles 22:8 · Berean Standard Bible

So while Jehu was executing judgment on the house of Ahab, he found the rulers of Judah and the sons of Ahaziah’s brothers who were serving Ahaziah, and he killed them.

Context

6bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria. Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́. 7Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. 8Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. 9Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sá pamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé, “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró. 10Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Juda run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.