Native Bible

2 Chronicles 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́;

2 Chronicles 22:5 in English

2 Chronicles 22:5 · Berean Standard Bible

Ahaziah also followed their counsel and went with Joram son of Ahab king of Israel to fight against Hazael king of Aram at Ramoth-gilead. But the Arameans * wounded Joram;*

Context

3Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. 4Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀. 5Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́; 6bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria. Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́. 7Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.