Native Bible

2 Chronicles 22:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, ọmọ ọmọbìnrin Omri.

2 Chronicles 22:2 in English

2 Chronicles 22:2 · Berean Standard Bible

Ahaziah was twenty-two * years old when he became king, and he reigned in Jerusalem one year. His mother’s name was Athaliah, the granddaughter of Omri.

Context

1Àwọn ènìyàn Jerusalẹmu mú Ahasiah, ọmọ Jehoramu tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Arabia sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. 2Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, ọmọ ọmọbìnrin Omri. 3Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. 4Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.