Native Bible

2 Chronicles 20:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà.

2 Chronicles 20:29 in English

2 Chronicles 20:29 · Berean Standard Bible

And the fear of God came upon all the kingdoms of the lands when they heard that the LORD had fought against the enemies of Israel.

Context

27Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. 28Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè. 29Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà. 30Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká. 31Báyìí ni Jehoṣafati jẹ ọba lórí Juda. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Asuba ọmọbìnrin Silihi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.