Native Bible

2 Chronicles 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.”

2 Chronicles 2:16 in English

2 Chronicles 2:16 · Berean Standard Bible

We will cut logs from Lebanon, as many as you need, and we will float them to you as rafts by sea down to Joppa. Then you can take them up to Jerusalem.”

Context

14Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ. 15“Nísinsin yìí, jẹ́ kí olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní alikama àti barle àti òróró Olifi náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí. 16Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.” 17Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600). 18Ó sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún (3,600) alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.