Native Bible

2 Chronicles 19:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”

2 Chronicles 19:11 in English

2 Chronicles 19:11 · Berean Standard Bible

Note that Amariah, the chief priest, will be over you in all that pertains to the LORD, and Zebadiah son of Ishmael, the ruler of the house of Judah, in all that pertains to the king. And the Levites will serve as officers before you. Act resolutely; may the LORD be with the upright!”

Context

9Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé. “Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù Olúwa. 10Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń sàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, pa á láṣẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyí, ìwọ kì yóò sì jẹ̀bi. 11“Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.