2 Kronika 18:33
2 Chronicles 18:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.”
2 Chronicles 18:33 in English
2 Chronicles 18:33 · Berean Standard Bible
However, a certain man drew his bow without taking special aim, and he struck the king of Israel between the joints of his armor. So the king said to his charioteer, “Turn around * and take me out of the battle, for I am badly wounded!”
Context
31Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, 32Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró. 33Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.” 34Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.