2 Kronika 18:25
2 Chronicles 18:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba,
2 Chronicles 18:25 in English
2 Chronicles 18:25 · Berean Standard Bible
And the king of Israel declared, “Take Micaiah and return him to Amon the governor of the city and to Joash the king’s son,
Context
23Nígbà náà Sedekiah ọmọ Kenaana lọ sókè ó sì gbá Mikaiah ní ojú. Ó sì béèrè pé, “Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” 24Mikaiah sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò ṣe ìwádìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sá pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.” 25Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba, 26Ó sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ, ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ” 27Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.