Native Bible

2 Chronicles 16:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.

2 Chronicles 16:12 in English

2 Chronicles 16:12 · Berean Standard Bible

In the thirty-ninth year of his reign, Asa became diseased in his feet, and his malady became increasingly severe. Yet even in his illness he did not seek the LORD, but only the physicians.

Context

10Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára. 11Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 12Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. 13Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, 14wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.