Native Bible

2 Chronicles 15:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.

2 Chronicles 15:14 in English

2 Chronicles 15:14 · Berean Standard Bible

They took an oath to the LORD with a loud voice, with shouting, trumpets, and rams’ horns.

Context

12Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn. 13Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin. 14Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè. 15Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri. 16Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní àfonífojì Kidironi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.