Native Bible

2 Chronicles 12:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti.

2 Chronicles 12:3 in English

2 Chronicles 12:3 · Berean Standard Bible

with 1,200 chariots, 60,000 horsemen,* and countless troops who came with him out of Egypt—Libyans, Sukkites, and Cushites.*

Context

1Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ìjọba Rehoboamu múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Israẹli, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì. 2Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu. 3Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti. 4Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó. 5Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.