2 Kronika 11:16
2 Chronicles 11:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn.
2 Chronicles 11:16 in English
2 Chronicles 11:16 · Berean Standard Bible
Those from every tribe of Israel who had set their hearts to seek the LORD their God followed the Levites to Jerusalem to sacrifice to the LORD, the God of their fathers.
Context
14Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa. 15Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, àti fún àwọn ère òbúkọ, àti fún ẹgbọrọ màlúù tí ó ṣe. 16Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn. 17Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí. 18Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.