Native Bible

2 Chronicles 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀.

2 Chronicles 11:12 in English

2 Chronicles 11:12 · Berean Standard Bible

He also put shields and spears in all the cities and strengthened them greatly. So Judah and Benjamin belonged to him.

Context

10Sora, Aijaloni, àti Hebroni. Wọ̀nyí ni àwọn ìlú ìdáàbòbò ní Juda àti Benjamini. 11Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì. 12Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀. 13Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákèjádò Israẹli wà ní ẹ̀bá rẹ̀. 14Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.