Native Bible

2 Chronicles 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ”

2 Chronicles 10:9 in English

2 Chronicles 10:9 · Berean Standard Bible

He asked them, “What message do you advise that we send back to these people who have spoken to me, saying, ‘Lighten the yoke your father put on us’?”

Context

7Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ìre fún wọn, kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.” 8Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbàgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbàsókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀. 9Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ” 10Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ. 11Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.