2 Kronika 1:14
2 Chronicles 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu.
2 Chronicles 1:14 in English
2 Chronicles 1:14 · Berean Standard Bible
Solomon accumulated * 1,400 chariots and 12,000 horses,* which he stationed in the chariot cities and also with him in Jerusalem.
Context
12Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.” 13Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli. 14Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu. 15Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè. 16Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.