1 Timotiu 3:4
1 Timothy 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo.
1 Timothy 3:4 in English
1 Timothy 3:4 · Berean Standard Bible
An overseer must manage his own household well and keep his children under control, with complete dignity.
Context
2Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. 3Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó. 4Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo. 5Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? 6Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.