Native Bible

1 Timothy 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.

1 Timothy 2:10 in English

1 Timothy 2:10 · Berean Standard Bible

but with good deeds, as is proper for women who profess to worship God.

Context

8Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. 9Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, 10bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run. 11Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́. 12Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.