Native Bible

1 Thessalonians 4:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀.

1 Thessalonians 4:15 in English

1 Thessalonians 4:15 · Berean Standard Bible

By the word of the Lord, we declare to you that we who are alive and remain until the coming of the Lord will by no means precede those who have fallen asleep.

Context

13Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí. 14A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá. 15Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀. 16Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde. 17Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.