1 Tẹsalonika 4:11
1 Thessalonians 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín.
1 Thessalonians 4:11 in English
1 Thessalonians 4:11 · Berean Standard Bible
and to aspire to live quietly, to attend to your own matters, and to work with your own hands, as we instructed you.
Context
9Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè. 13Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.