1 Tẹsalonika 3:6
1 Thessalonians 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.
1 Thessalonians 3:6 in English
1 Thessalonians 3:6 · Berean Standard Bible
But just now, Timothy has returned from his visit with the good news about your faith, your love, and the fond memories you have preserved, longing to see us just as we long to see you.
Context
4Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. 5Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán. 6Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá. 7Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa. 8Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.