Native Bible

1 Thessalonians 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìyìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa.

1 Thessalonians 2:8 in English

1 Thessalonians 2:8 · Berean Standard Bible

We cared so deeply that we were delighted to share with you not only the gospel of God, but our own lives as well. That is how beloved you have become to us.

Context

6A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín. 7Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, 8bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìyìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. 9Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín. 10Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.