Native Bible

1 Thessalonians 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.

1 Thessalonians 1:6 in English

1 Thessalonians 1:6 · Berean Standard Bible

And you became imitators of us and of the Lord when you welcomed the message with the joy of the Holy Spirit, in spite of your great suffering.

Context

4Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. 5Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín. 6Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín. 7Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia. 8Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.