1 Tẹsalonika 1:3
1 Thessalonians 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.
1 Thessalonians 1:3 in English
1 Thessalonians 1:3 · Berean Standard Bible
and continually recalling before our God and Father your work of faith, your labor of love, and your enduring hope in our Lord Jesus Christ.
Context
1Paulu, Sila àti Timotiu,
A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi:
Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín. 2Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú. 3A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa. 4Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀. 5Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.