Native Bible

1 Samuel 9:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “Ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

1 Samuel 9:27 in English

1 Samuel 9:27 · Berean Standard Bible

As they were going down to the edge of the city, Samuel said to Saul, “Tell the servant to go on ahead of us, but you stay for a while, and I will reveal to you the word of God.” So the servant went on.

Context

25Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Samuẹli sì bá Saulu sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀. 26Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, ó pe Saulu sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Saulu múra tán òun àti Samuẹli jọ jáde lọ síta. 27Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “Ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.