Native Bible

1 Samuel 9:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Saulu dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há ṣe ẹ̀yà Benjamini? Kékeré nínú ẹ̀yà Israẹli. Ìdílé mi kò ha rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹ̀yà Benjamini? Èéṣì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

1 Samuel 9:21 in English

1 Samuel 9:21 · Berean Standard Bible

Saul replied, “Am I not a Benjamite from the smallest tribe of Israel, and is not my clan the least of all the clans of Benjamin? So why would you say such a thing to me?”

Context

19Samuẹli dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ. 20Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dààmú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Israẹli wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.” 21Saulu dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há ṣe ẹ̀yà Benjamini? Kékeré nínú ẹ̀yà Israẹli. Ìdílé mi kò ha rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹ̀yà Benjamini? Èéṣì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?” 22Nígbà náà ni Samuẹli mú Saulu pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngán, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n. 23Samuẹli sọ fún alásè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.