1 Samuẹli 7:1
1 Samuel 7:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.
1 Samuel 7:1 in English
1 Samuel 7:1 · Berean Standard Bible
Then the men of Kiriath-jearim came for the ark of the LORD and took it into Abinadab’s house on the hill. And they consecrated his son Eleazar to guard the ark of the LORD.
Context
1Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa. 2Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí Olúwa. 3Samuẹli sọ fún gbogbo ilé Israẹli pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì àti Aṣtoreti kí ẹ sì fi ara yín jì fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.