1 Samuẹli 6:19
1 Samuel 6:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọlu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Beti-Ṣemeṣi, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà.
1 Samuel 6:19 in English
1 Samuel 6:19 · Berean Standard Bible
But God struck down some of the people of Beth-shemesh because they looked inside the ark of the LORD. He struck down seventy men,* and the people mourned because the LORD had struck them with a great slaughter.
Context
17Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Filistini fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Aṣdodu, ọ̀kan ti Gasa, ọ̀kan ti Aṣkeloni, ọ̀kan ti Gati, ọ̀kan ti Ekroni. 18Wúrà eku ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Filistini márààrún ti wá, ìlú olódi pẹ̀lú ìletò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Joṣua ará Beti-Ṣemeṣi. 19Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọlu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Beti-Ṣemeṣi, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà. 20Àwọn ọkùnrin ará Beti-Ṣemeṣi béèrè pé, “Ta ni ó le è dúró ní iwájú Olúwa Ọlọ́run mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò gbà gòkè lọ láti ibí yìí?” 21Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati-Jearimu wí pé, “Àwọn Filistini ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.